Welcome to Nigeria's No.1 Article Reading Platform.

Header Ads

Indigenous History: Ìtàn Mánigbàgbé: Bí Ẹfunroye Tinubu ṣe di ilú Ẹ̀gbá mú, ló ń pàṣẹ ní Eko

Ti a ba n sọrọ awọn akọni obinrin nilẹ Yoruba, ti a ko ba ti darukọ Iyalode akọkọ nilẹ Ẹgba, Ẹfunroye Tinubu, a jẹ pe itan naa ko ti kun ni.
Ni ilu Eko, Badagry ati Ẹgba, okiki arabinrin Ẹfunroye Tinubu tan kaakiri nitori pe ọlọla ni, o gbajumọ, to si tun jẹ gbajumọ onisowo ẹru, ọti oyinbo ati awọn ohun ija oloro.
Ko fẹẹ si ọba kankan laye Tinubu, ti yoo kọ iyan akọni obinrin naa, ti ko ni fi ewe boo, nitori pe alagbara ni, to si n fi ọba jẹ, bẹẹ lo n rọ ọba loye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹfunroye TinubuImage copyright@DRADROCKE
Gẹgẹ bi a ti se akojọ rẹ loju opo itakun agbaye, ibẹru Ẹfunroye Tinubu laye igba rẹ, ni ipilẹsẹ ọgbọn fun awọn oriade nilu Eko ati Ẹgba.

Awọn ohun to yẹ ko mọ nipa Ẹfunroye Tinubu:

  • Ọdun 1810 ni wọn bi Ẹfunpọroye Ọsuntinubu, eyi ti wọn ge kuru si Ẹfunroye Tinubu, ni igbo Ojokodo nilẹ Ẹgba. Orukọ baba rẹ ni Olumọsa lati Ẹgba Owu
  • Ẹfunroye se igbeyawo pẹlu ọkunrin pupọ, o si bi ọkunrin meji fun ọkọ aarọ rẹ to fẹ lati ẹya Owu
  • Nigba ti ọkọ rẹ akọkọ ku tan, lọdun 1833 lo tun fẹ Ọba Eko ti wọn le lori oye, Adele Ajosun, lasiko ti onitọun wa se abẹwo silu Abẹokuta, ti ẹwa Ẹfunroye si faa mọra
  • Ẹfunroye tẹle Ọba Adele pada silu Badagry, nitori ilu yii ni Ọba naa fori pamọ si, agbara Adele si ni Ẹfunroye lo lati mu ki okoowo siga, iyọ ati owo ẹru to n se fẹju si
  • Ọba Eko, Ọba Idewu jẹ ipe awọn baba rẹ, ti ọba Adele ti wọn le lori oye si pada lọ jọba ilu Eko, eyi to sọ Ẹfunroye di olori, bi o tilẹ jẹ pe ọba naa ko lo ju ọdun meji lọ to fi waja ni 1837
  • Oluwọle, tii se ọmọ ọba Adele gori itẹ, ti Ẹfunroye si fẹ Yesufu Bada Ọbadina. Pẹlu atilẹyin Ọba Oluwọle, tọkọ-taya tuntun yii gbọrẹgẹ-jigẹ ninu okoowo sise lagbegbe Ẹgba
  • Ọba Oluwọle waja lọdun 1841, Tinubu se atilẹyin fun Akitoye, aburo ọkọ rẹ, lati jẹ Ọba ilu Eko, Ọba yii si tun faaye gbaa lati mu ki okoowo rẹ burẹkẹ si
  • Kosọkọ le Akitoye lori itẹ lọdun 1845, ti Ẹfunroye Tinubu ati Akitoye si sa asala fun ẹmi wọn lọ si ilu Badagry, nibi ti okiki obinrin naa nidi ọrọ aje tun ti tan si
  • Losu Kejila ọdun1851 ni awọn eebo Gẹẹsi le Ọba Kosọkọ lori oye, ti Akitoye si tun pada sibẹ, lẹyin to ti tọwọ bọ iwe pe oun ko ni lọwọ ninu owo ẹru sise
  • Adehun yii ko ba Ẹfunroye Tinubu lara mu, to si n dọgbọn se owo ẹru labẹlẹ, to si n fi ẹru paarọ fawọn eebo Pọtugi ati Brazil lati gba ibọn
  • Lara awọn ilẹ ti Ẹfunroye Tinubu gba lọwọ Ọba Akitoye ni gbagede Tinubu (Tinubu Square) ati opopona Kakawa, to wa nilu Eko di oni
  • Aawọ nla bẹ silẹ laarin awọn onisowo ẹru ati Ẹfunroye nitori bi okoowo obinrin naa se n gbinlẹ, ti awọ̀n eebo si gba Ọba Akitoye nimọran lati le Ẹfunroye Tinubu kuro nilu Eko
  • Lẹyin ti Ọba Akitoye jẹ ipe awọn baba nla rẹ, Ọba Dosumu gori itẹ, ti Tinubu si pada silu Eko lati se atilẹyin fun, bẹẹni ọwọja okoowo rẹ ko dinku, o n fẹju si ni
  • Asiko Ọba Dosumu ni Tinubu ko ọpọ ọmọ ogun jọ, ninu eyi ti awọn ẹru wa, to si maa n ta asẹ ọba nipa nigba miran, eyi to mu ki ọrọ rẹ su ọba Dosumu
  • Ẹfunroye Tinubu se agbatẹru ijagboro kan to lagbara lati tako awọn ẹru to ni ominira, ti wọn pada de lati ilẹ Saro, idi si ree ti wọn tun fi le Ẹfunroye kuro ni Eko lọ si Abẹokuta
  • Ẹfunroye Tinubu di onisowo ibọn atawọn ohun ija oloro miran nilu Abẹokuta, to si pese ohun ija lati sẹgun ogun Dahomey, eyi to mu ki wọn fi jẹ Iyalode Ẹgba
  • Ẹfunroye ko gbe jẹ nilu Abẹokuta, to si tun lọwọ si ọrọ ọba jijẹ, to si n se atilẹyin fun Ọmọọba Oyekan lati yẹ aga ọba mọ Ọba Ademọla nidi gẹgẹ bii Alake tilẹ Ẹgba lọdun 1879
  • Iku pa oju Ẹfunroye Tinubu de lọdun 1887 ni agboole Ojokodo nilu Abẹokuta, ti wọn si fi ita Tinubu sọri rẹ
Awaye ku ko si, ọrun ma kanju, gbogbo wa la n bọ, ti ina yoo si dilẹ lẹyin asunsun jẹ.
A ba jẹ obinrin, tabi ọkunrin, o yẹ ka ranti pe isẹ ọwọ wa, yoo maa tọ wa lẹyin ta ba lọ tan.
Ohun ta ba se laye lo ja ju, tori naa, ẹjẹ ka gbe ile aye se rere nitori bo pẹ, bo ya, bi onirese wa ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ ko lee parun.
SOURCE: BBC.COM

Post a Comment

0 Comments