Welcome to Nigeria's No.1 Article Reading Platform.

Header Ads

Indigenous History: Ìtàn Mánigbàgbé: Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, jagun-jagun orí ẹṣin tí kò ṣe fi ṣeré


Yoruba maa n sọ pe a ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, nitori ko si ohun ti ko sẹlẹ ri.
Gẹgẹ baa ti ka ninu itan awọn nkan to ti sẹlẹ siwaju laye atijọ, awọn obinrin ti jẹ Alaafin ri, ti ko si gbọdọ jẹ ajeji si wa mọ lode oni.
Gẹgẹ ba ti ka itan rẹ lori itakun agbaye ati Wikipedia, Alaafin akọkọ to jẹ obinrin ni Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Itan naa ni bi ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii deede sẹ, bẹẹ si ni bi ko ba ni idi, obinrin kii jẹ Kumolu.
Aisi ọkunrin mọ to wa lati idile to n jẹ Alaafin lo fa sababi bi Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn se di ọba lode Ọyọ.

Bi itan Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn se lọ ree.

  • Apeja orukọ Alaafin akọkọ ni Aláàfin Àjíún Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, to si maa n ki ara rẹ ni 'Ajiun, a rí òbò sẹgun ọtẹ'
  • Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn jẹ Alaafin laarin ọdun 1554 si 1562, nigba ti ko si ọkunrin mọ ni idile ọba to lee jẹ Alaafin
  • Orukọ baba Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ni Alaafin Onigbogi, to n gbe ni ilẹ Ibariba, o tẹri gbasọ, ti arole rẹ, Alaafin Ofinran si jọba lẹyin rẹ
  • Nigba ti Alaafin ofinran wa lori itẹ, ni wọn pinnu lati kuro ni ilẹ Ibariba lọ si Ọyọ, to si ko awọn eeyan rẹ ati awọn aburo rẹ lọwọ, ti orukọ wọn n jẹ Ọmọọba Eguguoju, Ọmọọbabinrin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ati Ọmọọba Ajiboyede
  • Loju ọna ni ọkan lara olori Alaafin ofinran to loyun ti bi ọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọmọọba Tella Abiipa
  • Loju ọna ni Alaafin Ofinran ti waja, ti Alaafin Oguguoju si gori itẹ lẹyin rẹ, oun lo si lewaju awọn eeyan rẹ de ilu Ọyọ Igboho, ti wọn tẹdo si lẹyin irinajo ọlọjọ gbọọrọ, ibẹ naa si loun naa ku si pẹlu
  • Ọkunrin to kan to yẹ ko jọba ni Ọmọọba Ajiboyede, amọ ọmọde patapata ni, ti ọkunrin miran to tun wa nilẹ, Ọmọọba Tella Abiipa, si wa lọmọ irakoro, ti ko si tun si ọkunrin miran ni didle Alaafin to lee gun ori itẹ
  • Idi ree ti awọn Ọyọmesi, to jẹ Afọbajẹ, fi pinnu lati mu ọmọ oye laarin ara wọn, sugbọn ti obinrin kan soso to dagba ni idile ọba, Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn fi aake kọri, to si ni oun ni oun yoo gun ori itẹ Alaafin
  • Awọn Ọyọmesi naa taku pe eewọ, ko si ninu itan ri pe obinrin jẹ Alaafin, ti wọn si sọ fun Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn pe ko seese, afi ko jẹ ọkunrin ni yoo jẹ Alaafin
  • Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn wa seleri fun wọn pe oun yoo fi han wọn pe ọkunrin ni oun, oun kii se obinrin, ati idi ti oun fi lẹtọ lati jẹ ọba. O ni ki wọn pade oun ni ipebi ni ọjọ keje lati wa ri iran naa wo, to si bẹrẹ si ni wọ Agbada, buba ati sokoto bii ọkunrin lati igba naa lọ
  • Ni ọjọ keje, ẹnu ya awọn Ọyọmesi ni Ipebi, nigba ti Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn bọ ara rẹ silẹ fun wọn, ti wọn si ri pe ko si ọmu ni aya rẹ, bẹẹ si ni dipo nkan ọmọobinrin, nkan ọkunrin lo wa ni abẹ rẹ. Idi si ree to fi n ki ara rẹ ni 'Ajiun, a rí òbò sẹgun ọtẹ'
  • Kiakia ni wọn dọbalẹ fun, ti wọn si n se ni Kabiesi. Lẹyin eyi lo jẹ Alaafin ti igba rẹ tuba, tusẹ, to si sẹ oniruuru ogun fun ilu Ọyọ.
  • Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn gbowọ ninu lilo ohun ijagun, o jẹ jagunjagun to da musemuse, oun si ni ọbabinrin to sẹgun ogun awọn ẹya Nupe to maa n da Ọyọ laamu laarin ọdun 1555.
Ni aye ode oni, ẹkọ nla gidi ni itan igbe aye Alaafin obinrin akọkọ yii yẹ ko kọ wa, eyi to fi han wa pe ko si ohun ti ọkunrin lee se, ti obinrin ko lee se.
Bakan naa lo fi ye wa pe isẹ́ abẹ́ ko sẹsẹ bẹrẹ, o ti wa lati atetekọse, ti awn eeyan kan si gba pe Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ni ẹda akọkọ to jẹobinrin, amọ to yipada si ọkunrin, gẹgẹ bawọn eeyan kan se n se lode oni.

Oju orori Alaafin OronpotoniyunImage copyrightYORUBYTE

O wa yẹ ko ye gbogbo wa bayii pe, ka ma se ilakaka pe a ko bi ọkunrin, tabi obinrin nikan la n bi jọ, nitori gbogbo lọmọ, ko si eyi ti ko wulo ninu wọn.
CREDIT: BBC.COM

Post a Comment

0 Comments